Discover millions of ebooks, audiobooks, and so much more with a free trial

Only $11.99/month after trial. Cancel anytime.

Ìkẹtàlá Ti Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú
Ìkẹtàlá Ti Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú
Ìkẹtàlá Ti Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú
Ebook47 pages47 minutes

Ìkẹtàlá Ti Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú

Rating: 0 out of 5 stars

()

Read preview

About this ebook

Ìkẹtàlá Ti Megan ni ọ̀wọ́ kejì nínú mẹ́tàlélógún ti Ipele Megan. Ó jẹ́ ọjọ́ ìbí Megan tí ó ní agbára nínú ẹ̀mí. Láti ṣe àjọyọ̀ rẹ̀ pé ó da ọ[dọ́, àwọn òbí rẹ̀ nṣe àpèjẹ nlá kan fún u. Tẹbí tọ̀rẹ́ ni wọ́n pè síbi ayẹyẹ nlá náà, níbi tí olùṣètò orin tí ó jẹ́ akọni rẹ̀, Jack Hammer yóò ti gbé àwọn orin jáde. Ó ndà á rò bóyá ẹnikẹ́ni fi ojú sọ Grrr, àléjò rẹ̀ nlá tíí ṣe ànjọ̀nnú Ẹkùn ará ilẹ̀ Siberia. Kò máa níi ́lọ́kàn láti pàdé àlejò kan tí ó rẹwà lọ́kùnrin. Ipele Ti Megan wà fún àwọn ènìyàn láìfi ti ọjọ́ orí ṣe tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí.
LanguageYoruba
PublisherTektime
Release dateFeb 13, 2021
ISBN9788835418979
Ìkẹtàlá Ti Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú
Author

Owen Jones

Author Owen Jones, from Barry, South Wales, came to writing novels relatively recently, although he has been writing all his adult life. He has lived and worked in several countries and travelled in many, many more. He speaks, or has spoken, seven languages fluently and is currently learning Thai, since he lived in Thailand with his Thai wife of ten years. "It has never taken me long to learn a language," he says, "but Thai bears no relationship to any other language I have ever studied before." When asked about his style of writing, he said, "I'm a Celt, and we are Romantic. I believe in reincarnation and lots more besides in that vein. Those beliefs, like 'Do unto another...', and 'What goes round comes around', Fate and Karma are central to my life, so they are reflected in my work'. His first novel, 'Daddy's Hobby' from the series 'Behind The Smile: The Story of Lek, a Bar Girl in Pattaya' has become the classic novel on Pattaya bar girls and has been followed by six sequels. However, his largest collection is 'The Megan Series', twenty-three novelettes on the psychic development of a young teenage girl, the subtitle of which, 'A Spirit Guide, A Ghost Tiger and One Scary Mother!' sums them up nicely. After fifteen years of travelling, Owen and his wife are now back in his home town. He sums up his style as: "I write about what I see... or think I see... or dream... and in the end, it's all the same really..."

Read more from Owen Jones

Related to Ìkẹtàlá Ti Megan

Reviews for Ìkẹtàlá Ti Megan

Rating: 0 out of 5 stars
0 ratings

0 ratings0 reviews

What did you think?

Tap to rate

Review must be at least 10 words

    Book preview

    Ìkẹtàlá Ti Megan - Owen Jones

    Ẹ̀tọ́ Owen Jones láti di mímọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kọ ìwé yìí ni a ti tì bọ̀ ọ́ ní ìbámu pẹ̀lú abala 77 àti 78 ti Òfin Àṣẹ Àdáni Iṣẹ́ Ọnà àti Ẹ̀tọ́ ti Ọdún 1988. A ti ti ẹ̀tọ́ ìwà rere ti ònkọ̀wé bọ̀ ọ́.

    Nínú iṣẹ́ àròsọ yìí, àwọn ènìyàn àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ àbájáde àfinúrò ònkọ̀wé tàbí pé a lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àròsọ pọnbélé. Àwọn ibi kan lè wà, ṣùgbọ́n àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ àròsọ.

    Ẹ kàn sí mi ní:

    http://facebook.com/angunjones

    http://twitter.com/owen_author

    owen@behind-the-smile.org

    http://owencerijones.com

    Ẹ dara pọ̀ mọ́ àtẹ̀jáde wa àtìgbàdégbà fún ìfitónilétí abẹ́lé nípa àwọn ìwé àti àpilẹ̀kọ Owen Jones nípa títẹ adirẹsì imeeli yín níhin:

    http://meganthemisconception.com

    Àwọn ìwé àkàgbádùn kéékèèké míràn ní ipele kan náà:

    Àwọn Ipele Ti Megan

    Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!

    Àṣìrò Náà

    Ìkẹtàlá ti Megan

    Ìrìnàjò Megan Ní Ilé-ìwé

    Àwọn Ìdánwò Megan Ní Ilé-ìwé

    Àwọn Ọmọlẹ́yìn Megan

    Megan Pẹ̀lú Ológbò Náa Tí Ó Sọnù

    Megan àti Obìnrin Olórí Ìlú Náà

    Megan Dojú Kọ Ẹ̀gàn

    Ìbẹ̀wò Baba Àgbà Àti Ìyá Àgbà Megan

    Ara Baba Megan Ò Dá

    Megan Lọ Fún Ìsinmi

    Megan àti Fọ́léfọ́lé náà

    Megan àti Oníkẹ̀kẹ́ náà

    Megan àti Ìyá Arúgbó náà

    Ọgbà Megan

    Megan Lọ Sí Ọgbà Àwọn Ẹranko

    Megan Rin Ìrìn Afẹ́ Lọ

    Megan àti Ìdíje Onjẹ Sísè W. I.

    Megan Wakọ̀ Lo

    Megan Lọ Wa Ọkọ̀ Ojú Omi

    Megan níbi Àjọ̀dún

    Megan níbi Ọdún Keresimesì

    ÌFISỌRÍ

    Mo fi ìwé yìí sọrí àwọn òbí mi Colin àti Marion fún bí wọ́n ti tọ́ èmi àti àwọn arákùnrin mi dàgbà ní ọ̀nà ìyanu.

    ÀWỌN ÀKÓÓNÚ

    ÌMỌYÌ

    Mo fẹ́ mọ rírì ìrànlọ́wọ́ aya mi àti ọ̀rẹ́ mi David Prosser fún iṣẹ́ ọnà ẹ̀yìn ìwé náà.

    ÌYÀLẸ́NU ÌYÁ

    Ìyá Megan, Susanne, ti jẹ́ obìnrin ọ̀tọ̀ láti ìgbà tí ó ti ti Megan mọ́ ibi tí wọ́n nkó èédú pamọ́ sí kẹ́yín ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn. Ó mọ̀ pé Megan ṣì lè sọ fún baba rẹ̀ nípa rẹ̀ nígbàkígbà, ṣùgbọ́n bí ó ti njìnnà sí ọjọ́ búburú náà síi, ó túbọ̀ nnira fún Megan láti ṣe bẹ́ẹ̀. Megan ti yọ ọ́ kúrò nínú ọ̀fìn, ó sì mọ̀ pé òun jẹ ẹ́ ní nnkan kan nítorí ìyẹn. Bákan náà, ó dàbí ẹni pé Megan ti ṣíwọ́ nípa sísọ nípa àwọn agbára rẹ̀ nínú ẹ̀mí, tí kìí ṣe ojú lásán, kò sá sọ ọ́ níwájú ìyá rẹ̀ mọ́.

    Pẹ̀lú ojú tí Megan fi wò ó, níkẹyìn ìyá rẹ̀ tún ti da ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ kí ó wà ní gbogbo ìgbà tẹ́lẹ̀, nínú àfẹnukò àmọ̀sínú tìyá-tọmọ. Megan ti ní ìmọ̀lára pé, ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ìyá òun ti ní ìfòyà pé òun yóò lo ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti halẹ̀ mọ́ ọ láti rí ojúrere rẹ̀. Ó mọ̀ pé ohun tí ìyá òun nrò nípa òun nìyẹn tí ó sì ndùn ú. Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí kò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ìyá rẹ̀ tún ti bẹ̀rẹ̀ síí fi ara mọ́ ọ. 

    Ní àkọ́kọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ jọ ara wọn, ṣùgbọ́n díẹ̀díẹ̀, ìtẹ̀síwájú bẹ̀rẹ̀ síí wáyé.

    Megan àti ìyá rẹ̀ ní ìmọ̀lára ‘Ọ̀rọ̀ Àjọsọ’ yìí dáradára, ṣùgbọ́n Megan ni ó gbé e ró kìí ṣe ìyá rẹ̀. Megan rò pé òun dìídì nṣe ojúṣe ọmọ sí òbí.

    Ó nbá ìyá rẹ̀ se onjẹ, ó sì nbá a tẹ́ ibùsùn. Ó nbá a gbé ọjà tí ó bá rà. Nígbà tí ìyá rẹ̀ bá sì nbójútó ọgbà ẹ̀fọ́, ó máa ngbìyànjú láti wá àkókò láti bá a ṣiṣẹ́. Suzanne ò ṣe nnkan kan bàbàrà, nítorí pé ó nretí pé kí gúdúgbẹ̀ já. Ní ọ̀nà tààrà, kò ní èrò láti ríi pé Megan ò mọ̀ọ́mọ̀ já òun kulẹ̀. Sùgbọ́n Megan mọ ohun tí ìyá òun nrò, pé ó ṣeéṣe kí ó ti mọ èrò ọkàn òun ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

    Ẹ̀wẹ̀, ní òwúrọ̀ Ọjọ́ Àbámẹ́ta kan níbi onjẹ òwúrọ̀, ní ọ̀sẹ̀ kan

    Enjoying the preview?
    Page 1 of 1