Discover millions of ebooks, audiobooks, and so much more with a free trial

Only $11.99/month after trial. Cancel anytime.

Lati Inu Dáyárì Ọmọ Kilásì Àárin Kan: Iriri Ọmọde
Lati Inu Dáyárì Ọmọ Kilásì Àárin Kan: Iriri Ọmọde
Lati Inu Dáyárì Ọmọ Kilásì Àárin Kan: Iriri Ọmọde
Ebook62 pages56 minutes

Lati Inu Dáyárì Ọmọ Kilásì Àárin Kan: Iriri Ọmọde

Rating: 0 out of 5 stars

()

Read preview

About this ebook

Àpèjúwe Kúkúrú
Ninu ìwé yii Mo ti ṣàpèjúwe awọn akitiyan igbé ayé mi ni kọlẹji. Mo pinnu lati kọ ìwé yi nigbati ó jẹ wipe n kò ni awọn ọrẹ, n kò mọ bi awọn ìdánwò ipari simẹsità ti yunifásítì se ri, ti mo si pàdánù awọn ìdánwò mi. Lẹhin ọpọlọpọ akitiyan, mo se awọn ìdánwò ipari simẹsità, mo si kọ awọn iriri mi ni kọlẹji sinu ìwé yi.


Àpèjúwe Ní Kíkún
Ninu ìwé yii Mo ti ṣàpèjúwe awọn akitiyan igbé ayé mi ni kọlẹji. Mo pinnu lati kọ ìwé yi nigbati ó jẹ wipe n kò ni awọn ọrẹ, n kò mọ bi awọn ìdánwò ipari simẹsità ti yunifásítì se ri, ti mo si pàdánù awọn ìdánwò mi. Lẹhin ọpọlọpọ akitiyan, mo se awọn ìdánwò ipari simẹsità, mo si kọ awọn iriri mi ni kọlẹji sinu ìwé yi.
LanguageYoruba
PublisherTektime
Release dateSep 8, 2021
ISBN9788835427162
Lati Inu Dáyárì Ọmọ Kilásì Àárin Kan: Iriri Ọmọde
Author

Ashok Kumawat

Ashok Kumawat was born in 1998 in Emri, a small village in the state of Rajasthan, India. He started writing from college life itself. He completed his education from government schools and colleges. He completed his master's degree in chemistry in 2021. He was always very smart in studies. He chose the medium of writing to do public service. He started writing in the last semester of his master's degree. He has written many books till now. It has always been his dream that more and more people read the books written by him. He wants people to be inspired by his books, he should bring some good changes in the world in his lifetime. He is a very religious person and likes to lead a quiet life.

Related categories

Reviews for Lati Inu Dáyárì Ọmọ Kilásì Àárin Kan

Rating: 0 out of 5 stars
0 ratings

0 ratings0 reviews

What did you think?

Tap to rate

Review must be at least 10 words

    Book preview

    Lati Inu Dáyárì Ọmọ Kilásì Àárin Kan - Ashok Kumawat

    Lati Inu Dáyárì Ọmọ Kilásì Àárin Kan

    Iriri Ọmọde

    Ashok Kumawat

    Itumọ lati Samson Adeyekun

    ©2021Ashok Kumawat.

    Gbogbo ẹtọ ni a gbà.  Ẹnikẹni kò gbọdọ da ohunkóhun kọ, sègbàsilẹ, tabi se ẹdà iwé yii nipasẹ ẹrọ tàbi ni ọnàkọnà lai gba àsẹ fún sise bẹẹ lati ọwọ atẹwétà

    31 Osù Keje, Ọdún 2018 4

    Ọjọ́ Kíni Oṣù Kẹjọ, Ọdún 2018 12

     Ọjọ Kẹrin Oṣù Kẹjọ, Ọdún 2018 15

    Ọjọ́ Karùn-ún Oṣù Kẹjọ, 2018 21

    Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹjọ, Ọdún 2018 27

    Ọjọ Keje Oṣù Kẹjọ, Ọdún 2018 28

    Ọjọ́ Kẹjọ Oṣù Kẹjọ, Ọdún 2018 32

    Ọjọ Kẹẹdógun Oṣù Kẹjọ, Ọdún August 2018 36

    Ọjọ Kọkànlélọgbọn Oṣù Kẹjọ, Ọdún 2018 38

    Ọjọ Kẹwàá Oṣù Kọkànlá, Ọdún 2018 46

    Ogun’jọ́ Oṣù Kejìlá, Ọdún 2018 49

    Ogúnjọ́ Oṣù Keji, Ọdún 2019 51

    Ọjọ Keji Oṣù Kejìlá, Ọdún 2019 54

    Ọjọ Kẹji Osù Karùn-ún, Ọdún 2020 57

    Ọjọ Kẹwa Osù Kẹsàn-án, Ọdún 2020 59

    Ọjọ Kẹẹdógún Oṣù Kejìlá, Ọdún 2020 67

    Ọjọ Kọkàndínlógún Osù Kẹfà, Ọdún 2021 73

    1

    31 Osù Keje, Ọdún 2018

    Aago mẹrin àárọ ló lù.  Gbogbo ara ile mi ni idániji alágbèéká ji kalẹ.  Iya mi pa idániji naa, o si ji mi dide lori ibusun.  Baba mi lọ sábẹ àgọ́ lati fun wàrà mààlúù.  O saabà máa nlọ sabẹ agọ maaluu laraarọ ni aago marun, sugbon ó tètè jáde lóni.  Agọ maaluu naa jin tó mita Igba lati ilé wa.  Eyi ni ipààlà ògiri ti a fi okuta funfun se ti o tàn kaakiri igun mẹrin lọgbọọgba yika Ẹgbẹrún-kan-lé-ẹgbẹrin-ó-din-áàdọta (1750) iwọn ẹsẹ. Igi kasià ni wọn fi se ẹnu ọnà àgọ́ mààlúù naa.  Mààlúù kan ati ọmọ rẹ̀ kan ló ngbé ninu àkámọ́ ògiri yen.  Abala àgọ́ ẹranko náà ní òrùlé, abala yoku wà ni sísí.  Tánkì omi kan wà fun àwọn ẹranko, pẹlú yàrá kan fun oúnjẹ wọn.  Nibòmiràn òkúta ni wọn fi se ilẹ rẹ.̀  Wọn fi erùpẹ kún àlàfo tó kù.  Kò si àyè fún iná mọnàmọná.  Nitorinà, gbogbo iṣẹ ni wọn ni lati se pẹlú iná bátírì.  

    Ni idàkeji, ni ilé ìyá mi sọ fún mi ki ntètè bomi s’ára ki nmúra sile.  Nítòótọ ọjọ òní jẹ ọjọ tó yàtọ.̀ Lónì mo ni láti lọ si yunifásítì fún iwọlé ikẹkọ fún M.Sc.. Nitorinà lónì wọn ti tètè ji èmi náà.  Mo dide lórí ibùsùn mi, ṣáájú mo rántí Ọlọrun lọkàn mi mo sì gbàdúrà sí i – Oluwa mi Krishna!  Lónìí mo ni láti gba ìwọlé fún ẹkọ́ ni kọlẹẹjì tuntun.  Máṣe jẹki ohunkóhun bà mi jẹ́ lónì.  Jọwọ dáábòbò mi kúrò lọwọ ojú búburú àti ìdènà.   

    Lẹhin àdúrà náà, mo fọ ẹhín mi.  Nígbàtí mo sèyí tán, mo lọ sílé iwẹ̀lati wẹ.̀  Titi di asikò náà ìyá mi ti bẹrẹ si pèsè oúnjẹ àárọ̀ fún mi.  Àwọn yàrá mẹta àti ilé iwẹ kan ló wà nílé mi.  A wá lati ìpín àárín ni ìdílé mi.  Ilé wa kò tóbi jù rárá.  Ṣugbọn gbogbo ìdílé wa ngbé pẹlú idẹra nínú ilé kékeré yi.  Biriki àti símẹntì ni wọn fi kọ ilé yi.  Ilé alájà kan ni ilé yi. Yàrá méjì ati ilé iwẹ kan wà ni ìsàlẹ,̀ yàrá kan wà ni òkè.  Yàrá tó wà lókè ló ṣe pàtàkì jùlọ.  Yàrá tiwa gan an niyi.  Mo ngbé inu yàrá kan nísàlẹ.̀  Yàrá yi dára púpọ.̀ Awọn iná mẹta àti fáánù kan ló wà nínú yàrá mi.  Àwọn oríṣiríṣi nkan mèremère ni wọn fi pamọ síbẹ.  Mo fẹràn yàrá mi yii.  Ilé iwẹ wà l'ẹgbẹ yàrá mi.  Yàrá kan wà l'ẹgbẹ ilé iwẹ yẹn tí a npè ni yàrá ikẹrùsi.  Fáánù kan ati ina méjì wà nínú yàrá ikẹrùsi yẹn.  Sugbọn yàrá yi kò lẹwà.  Nkò fẹràn yàrá yi rárá.  Yàrá gan an ni iná mẹta, fáánù, amúlétutù, fíríjì, amóhùnmáwòrán ati bẹẹbẹẹlọ.  Sugbọn mo fẹràn yàrá mi jù wọn lọ.

    Iyá mi ti wá oúnjẹ àárọ nigbàyẹn. Upma ni ó wá fún oúnjẹ àárọ. Ni asikò yii, baba mi náà ti dé lati ibi àgọ́ mààlúù. Nigbà náà ni iyá mi po tíì lori sitófù gásì kan ti ó si gbé wàrà ka'ná lóri sitófu miràn. Mo mu wàrà ati upma gbigbóná fún oúnjẹ àárọ. Mo fẹràn àdàpọ yii gan an ni. Ni idakeji, Baba mi naa múra sílẹ lẹhin ti ó ti wẹ tán.  Lẹhinna, ó mu tíì ati oúnjẹ àárọ. Ó dàbi pé gbogbo ilé ló máa nmu Tíà ni Indià. Sùgbọn  n kò fẹràn tíì. Èmi kì í mu tíì; bi ó tilẹ jẹ wipé tíì jẹ olókìkí gidigidi. Ọpọlọpọ èniyan nmu kọọbù mẹwàá si méjilá lójoojúmọ. Orisirisi tíì ni wọn nse ni Indià. Adùn tíì Masala nyanilẹnu. Èmi kì í mu tíì bi ó tilẹ jẹ wipé ohun tó dára ni. Mó siwọ tíì

    Enjoying the preview?
    Page 1 of 1